#OrinIhinrere: Yoruba Hymn Lyrics – OLUWA ORUN ON AIYE

Verse 1:

Oluwa orun oun aye
Wo niyin at’ ope ye fun
Bawo la ba ti fe O to
Onibu ore

Verse 2:

Orun ti nran at’ afefe
Gbogbo eweko nso fe Re
Wo l’O nmu irugbin dara
Onibu ore

Verse 3:

Fun ara lile wa gbogbo
Fun gbogbo ibukun aye
Awa yin O, a si dupe
Onibu ore

Verse 4:

O ko du wa li Omo re
O fi fun aye ese wa
Osi f’ebun gbogbo pelu
Onibu ore

Verse 5:

O fun wa l’Emi Mimo re
Emi iye at’agbara
O ro’ jo ekun ibukun re
Le wa lori

Verse 6:

Fun idariji ese wa,
Ati fun ireti orun
Ki lohun ta fin fun o
Onibu ore

Verse 7:

Owo ti a nna, ofo ni
Sugbon eyi ta fi fun o
O je isura tit’ aye
Onibu ore

Verse 8:

Ohun ta bun O Oluwa
Wo O san le pada fun wa
Layo la o ta O lore
Onibu ore

Verse 9:

Ni odo re l’a ti san wa
Olorun Olodumare
Je ka le ba O gbe titi
Onibu ore

Leave a Reply

Fill in your details below or click an icon to log in:

WordPress.com Logo

You are commenting using your WordPress.com account. Log Out /  Change )

Google photo

You are commenting using your Google account. Log Out /  Change )

Twitter picture

You are commenting using your Twitter account. Log Out /  Change )

Facebook photo

You are commenting using your Facebook account. Log Out /  Change )

Connecting to %s